Ẹniti ó bá pade Ọlọhun ni ẹniti kò mú orogun kankan pẹlu Rẹ̀, onitọhun yoo wọ Alujanna, ṣugbọn ẹniti ó bá pade Rẹ̀ ni ẹniti ó mú orogun pẹlu Rẹ̀, onitọhun yoo wọ Ina

Ẹniti ó bá pade Ọlọhun ni ẹniti kò mú orogun kankan pẹlu Rẹ̀, onitọhun yoo wọ Alujanna, ṣugbọn ẹniti ó bá pade Rẹ̀ ni ẹniti ó mú orogun pẹlu Rẹ̀, onitọhun yoo wọ Ina

Lati ọdọ Jabir ọmọ Abdullah - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - ó sọ pé: Mo gbọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti n sọ pe: "Ẹniti ó bá pade Ọlọhun ni ẹniti kò mú orogun kankan pẹlu Rẹ̀, onitọhun yoo wọ Alujanna, ṣugbọn ẹniti ó bá pade Rẹ̀ ni ẹniti ó mú orogun pẹlu Rẹ̀, onitọhun yoo wọ Ina".

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye pé ẹnikẹni tí ó bá kú, tí kò mu orogun kankan pẹlu Ọlọhun, Alujanna ni ibupadasi rẹ̀ kódà bí wọ́n bá jẹ ẹ niya nitori apakan ninu awọn ẹṣẹ rẹ̀, ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba ku, ni ẹniti n mu orogun pẹlu Ọlọhun, onitọhun yoo wọ inu Ina gbere.

فوائد الحديث

Ọla tí ń bẹ fun ìṣọlọ́hun-lọ́kan, ati pé ó jẹ́ òkùnfà fún ìgbàlà kúrò nibi wíwọ inu Ina gbere.

Isunmọ Alujanna ati Ina sí ọmọniyan, ati pé kò sí nkankan laarin ọmọniyan ati awọn mejeeji bikoṣe iku.

Iwani ní iṣọra kuro nibi ẹbọ, kekere rẹ̀ ati pupọ rẹ̀; nítorí pe jijina si ẹbọ ni ọna igbala kuro nibi wíwọ Ina.

Ariwoye inu awọn iṣẹ ni igbẹyin rẹ̀.

التصنيفات

Ida ọrọgun pọ mọ Ọlọhun, Awọn iroyin alujanna