“Dájúdájú àwọn èèyàn kan n wọ inu dúkìá Ọlọhun ni ọ̀nà tí kò tọ́, wọn maa wọ iná ni Ọjọ́ Àjíǹde”

“Dájúdájú àwọn èèyàn kan n wọ inu dúkìá Ọlọhun ni ọ̀nà tí kò tọ́, wọn maa wọ iná ni Ọjọ́ Àjíǹde”

Lati ọdọ Khaolah Al-Ansaariyyah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: “Dájúdájú àwọn èèyàn kan n wọ inu dúkìá Ọlọhun ni ọ̀nà tí kò tọ́, wọn maa wọ iná ni Ọjọ́ Àjíǹde”.

[O ni alaafia] [Bukhaariy gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ nipa awọn eeyan kan ti wọn n ṣe ibajẹ ninu dúkìá àwọn Musulumi, ti wọn si n mu u ni ọ̀nà ti kò tọ́, eyi ni itumọ kan ti o kari nibi dukia, nibi kiko o jọ lati ibi ti ko ti ni ẹtọ, ati nina an sibi ti kii ṣe aaye rẹ ti o tọ, jíjẹ dúkìá àwọn ọmọ orukan maa wọ inú ẹ, àti awọn dúkìá ti a fi sọri awọn kan, ati titako agbafipamọ, ati mimu ninu dúkìá gbogbogboo ni ọ̀nà tí kò tọ́. Lẹ́yìn náà ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé ẹsan wọn ni iná ni Ọjọ́ Àjíǹde.

فوائد الحديث

Dúkìá Ọlọhun ni dúkìá ti o wa ni ọwọ àwọn èèyàn, O fi wọn rólé nibẹ lati maa na an ní ọ̀nà tí ó bá òfin mu, ki wọn si jinna si ṣíṣe e kúmọkùmọ, èyí kárí gbogbo alaṣẹ ati awọn ti wọn yatọ si wọn ninu awọn èèyàn.

Líle sharia níbi dúkìá gbogbogboo, ati pe ẹni ti o ba jẹ alaṣẹ lori nǹkan kan ninu ẹ, onítọ̀hún maa ṣe ìṣirò bi o ṣe gbà á ati bi o ṣe na an ni Ọjọ́ Àjíǹde.

Ẹni tí ó n ṣe nnkan ti ko ba ofin mu ninu dúkìá naa maa ko sinu àdéhùn ìyà naa, bóyá o jẹ dúkìá rẹ ni tabi dúkìá ẹlòmíràn.

التصنيفات

Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ, Aleebu ini ifẹ aye