“Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara wé àwọn ènìyàn kan jẹ́ ọ̀kan nínú wọn.”

“Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara wé àwọn ènìyàn kan jẹ́ ọ̀kan nínú wọn.”

Lati ọdọ Ibnu Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara wé àwọn ènìyàn kan jẹ́ ọ̀kan nínú wọn.”

[O daa] [Abu Daud ati Ahmad ni wọ́n gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ẹni ti o ba fara wé àwọn èèyàn kan ninu awọn keferi, tabi awọn arúfin, tabi awọn ẹni rere- pẹ̀lú pe ki o ṣe nǹkan kan ninu awọn ìròyìn ti a mọ̀ wọn mọ̀ nibi adisọkan, tabi awọn ijọsin tabi awọn àṣà - ọkan ninu wọn ni; tori pé àfarawé wọn lóde máa ń yọrí sí àfarawé wọn ní inú, kò sì sí àní-àní pé àfarawé àwọn èèyàn máa ń jẹyọ latara ìjọlójú ni. Ó sì lè jẹ́ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ wọn, kí wọ́n sì máa gbé wọn tobi, kí wọ́n sì tẹ̀ sí ọ̀dọ̀ wọn, èyí sì lè mú kí èèyàn máa fara wé wọn titi dori inú ti o pamọ àti ìjọsìn – ki Ọlọhun ṣọ wa kúrò nibẹ-.

فوائد الحديث

Ikilọ kuro nibi ifarawe àwọn keferi ati awọn obilẹjẹ.

Ṣiṣenilojukokoro lori fifi ara we àwọn ẹni rere ati ikọṣe wọn.

Ìṣe àfarawé ni gbangba maa n jẹ ki èèyàn nífẹ̀ẹ́ dé inú.

Ọmọniyan maa tọ́ si àdéhùn ìyà ati ẹṣẹ bi o ba ṣe ṣe àfarawé tó ati irú ìran àfarawé ti o ba ṣe.

Kikọ afarawe awọn alaigbagbọ ninu ẹsin wọn ati ninu awọn aṣa wọn ti o jẹ ti wọn nìkan ni, ṣùgbọ́n nibi ohun ti ko ba ri bẹẹ, gẹgẹ bii kikọ iṣẹ ṣíṣe àwọn nǹkan ati iru bẹẹ, ko si ninu eewọ naa.

التصنيفات

Afijọ ti a kọ kuro nibẹ