إعدادات العرض
“Ẹ maa ṣe idẹkun fun awọn èèyàn, ẹ ma ṣe fi ara ni wọn, ẹ maa fun awọn èèyàn ni ìró ìdùnnú, ẹ ma ṣe lé wọn sá”
“Ẹ maa ṣe idẹkun fun awọn èèyàn, ẹ ma ṣe fi ara ni wọn, ẹ maa fun awọn èèyàn ni ìró ìdùnnú, ẹ ma ṣe lé wọn sá”
Lati ọdọ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹ maa ṣe idẹkun fun awọn èèyàn, ẹ ma ṣe fi ara ni wọn, ẹ maa fun awọn èèyàn ni ìró ìdùnnú, ẹ ma ṣe lé wọn sá”.
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी සිංහල ئۇيغۇرچە Kurdî Hausa Português മലയാളം తెలుగు မြန်မာ ไทย Deutsch 日本語 پښتو Tiếng Việt অসমীয়া Shqip Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands Kiswahili தமிழ் دری Magyar Italiano ಕನ್ನಡ Кыргызча Lietuvių Malagasy Română Kinyarwanda नेपाली Српски Soomaali Moore Українська Български Wolof Azərbaycan ქართული тоҷикӣ bmالشرح
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n pàṣẹ ki a maa ṣe idẹkun fun awọn èèyàn, ki a si ma fi ara ni wọn nibi gbogbo àlámọ̀rí ẹsin ati ayé, ìyẹn nibi ààlà nǹkan ti Ọlọhun ṣe ni ẹtọ ti O si ṣe ni ofin. O n ṣeni lojukokoro lati maa fun wọn ni iro ìdùnnú nipa oore, ki a si ma le wọn sa kuro nibẹ.فوائد الحديث
Ojuṣe onigbagbọ ododo ni ki o jẹ ki awọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ Ọlọhun, ki o si maa ṣe wọn ni ojúkòkòrò lati ṣe rere.
O tọ́ fun olupepe si ọdọ Ọlọhun ki o fi ọgbọ́n wo ọ̀nà ti yoo gba mu ipepe Isilaamu de ọdọ àwọn èèyàn.
Ifunni ni iro ìdùnnú maa n bi ìdùnnú ati ìkọjúsí ati ifọkanbalẹ fun olupepe ati fun nǹkan ti o n fi han àwọn èèyàn.
Ifi-ara-ni àwọn èèyàn maa n bi sísá, ati ìkọ̀yìnsí, ati mimu àwọn èèyàn maa ṣe iyèméjì nibi ọ̀rọ̀ olupepe.
Gbígbòòrò aanu Ọlọhun fun awọn ẹru Rẹ, ati pe O yọnu si ẹsin kan ti o rọrùn fun wọn, ati ofin ti wọn ṣe ni irọrun.
Ṣíṣe idẹkun ti wọn pàṣẹ rẹ naa ni ohun ti sharia mu wá.
التصنيفات
Awọn iwa ẹyin