“Gbogbo ìjọ mi ni yoo wọ alujanna ayafi ẹni tí ó bá kọ̀

“Gbogbo ìjọ mi ni yoo wọ alujanna ayafi ẹni tí ó bá kọ̀

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Gbogbo ìjọ mi ni yoo wọ alujanna ayafi ẹni tí ó bá kọ̀”, wọn sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ta ni o maa kọ̀? O sọ pe: “Ẹni ti o ba tẹle àṣẹ mi yoo wọ alujanna, ẹni tí ó bá yapa àṣẹ mi ti kọ̀”.

[O ni alaafia] [Bukhaariy gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe gbogbo ìjọ òun ni yoo wọ alujanna ayafi ẹni tí ó bá kọ̀! Awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- wa sọ pé: Ta ni ẹni tí ó máa kọ̀ irẹ ojiṣẹ Ọlọhun?! O da wọn lohun pe: Ẹni ti o ba tẹle àṣẹ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa wọ alujanna, ṣùgbọ́n ẹni tí o ba yapa ofin sharia ti kọ̀ lati wọ alujanna pẹ̀lú iṣẹ burúkú rẹ.

فوائد الحديث

Itẹle ojiṣẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ninu itẹle Ọlọhun, yiyapa rẹ naa si wa ninu ìyapa Ọlọhun.

Itẹle Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa sọ alujanna di dandan, yiyapa rẹ maa sọ iná di dandan.

Ìró ìdùnnú fun awọn olutẹle ninu ijọ yii pe gbogbo wọn ni wọ́n maa wọ alujanna ayafi ẹni tí ó bá yapa Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ.

Aanu Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fun ìjọ rẹ, ati ojúkòkòrò rẹ lati fi wọn mọ̀nà.

التصنيفات

Anọbi wa Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-