emi ni Dimaam ọmọ Tha’labah, láti ìdílé Banuu Sahd ọmọ Bakr

emi ni Dimaam ọmọ Tha’labah, láti ìdílé Banuu Sahd ọmọ Bakr

Láti ọ̀dọ̀ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Nígbà tí a jokoo pẹlu Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nínú mọṣalaaṣi, ọkùnrin kan ba wọlé lórí ràkúnmí, o da ràkúnmí rẹ̀ gunlẹ, o si dè é, lẹ́yìn naa o sọ fún wọn pé: Èwo ni Muhammad nínú yin? Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- si rọ̀gbọ̀kú láàrin wọn, ni a wa sọ pé: Ọkunrin pupa ti o rọ̀gbọ̀kú yii ni. Arákùnrin naa wa sọ fún un pé: Irẹ ọmọ Abdul Muttọlib, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: “Mo ti da ẹ lóhùn”. Arákùnrin naa wa sọ fún Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Maa bi ọ léèrè, ti mo si ma le mọ́ ọ lori ìbéèrè naa, ma ṣe bínú sí mi. O wa sọ pe: “Bèèrè ohun ti o ba fẹ”, o wa sọ pé: Mo fi Oluwa rẹ bẹ ọ ati Olúwa àwọn ti wọn ṣiwaju rẹ, ǹjẹ́ Ọlọhun ni O ran ọ si gbogbo àwọn èèyàn? O sọ pe: “Bẹẹni”. O sọ pe: Mo n fi Ọlọhun bẹ ọ, ǹjẹ́ Ọlọhun ni O pa ọ láṣẹ ki a maa ki irun wákàtí márùn-ún ni ojúmọ́? O sọ pe: “Bẹẹni”. O sọ pé: Mo n fi Ọlọhun bẹ ọ, njẹ Ọlọhun ni O pa ọ láṣẹ ki a maa gba aawẹ oṣù yii nínú ọdún? O sọ pe: “Bẹẹni”. O sọ pe: Mo n fi Ọlọhun bẹ ọ, njẹ Ọlọhun ni O pa ọ láṣẹ ki o gba sàká yii lọ́wọ́ àwọn olówó wa ki o si pin in fun awọn talika wa? Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: “Bẹẹni”. Arákùnrin naa wa sọ pé: Mo gba ohun ti o mu wa gbọ́, èmi si ni ojiṣẹ fun awọn ijọ mi, emi ni Dimaam ọmọ Tha’labah, láti ìdílé Banuu Sahd ọmọ Bakr.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- n sọ pé: Nígbà tí àwọn saabe jókòó pẹ̀lú Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nínú mọṣalaaṣi, ni ọkùnrin kan ba wọlé lórí ràkúnmí, o wa da a gunlẹ, lẹ́yìn náà o si dè é, Lẹ́yìn naa o bi wọn leere pé: Ewo ninu yin ni Muhammad? Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- rọgbọku láàrin àwọn èèyàn, ni a wa sọ pé: Ọkunrin pupa ti o rọgbọku yii ni, Ọkunrin naa sọ fun un pe: Iwọ ọmọ Abdul Muttalib, Ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ fún un pé: Mo gbọ́ ẹ, bèèrè, maa da ẹ lóhùn. Arákùnrin naa wa sọ fún Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Dajudaju èmi maa bi ọ léèrè, mo si maa le mọ́ ọ nibi ibeere naa, ma ṣe binu si mi. Ìtumọ̀ ni pé: Ma bínú si mi, ma si jẹ ki ipọnju ba ọ, O sọ pé: Beere ohun ti o fẹ, O wa sọ pe: Mo n fi Olúwa rẹ àti Olúwa àwọn ti wọn ṣáájú rẹ bẹ̀ ọ́, ǹjẹ́ Ọlọhun ni O ran ọ si awọn èèyàn? O sọ pé: Bẹẹni, lati fi kanpá mọ́ òdodo rẹ, Ọkùnrin náà sọ pé: ANSHUDUKA BILLAAH, itumọ rẹ ni pé: Mo n fi Ọlọhun bẹ ọ, ǹjẹ́ Ọlọhun ni O pa ọ láṣẹ ki a maa ki ìrun wákàtí márùn-ún ni ojúmọ́? Àwọn náà ni àwọn irun ọran-anyan, O sọ pe: Beeni, O sọ pe: Mo n fi Ọlọhun bẹ ọ, njẹ Ọlọhun ni O pa ọ láṣẹ ki a maa gba aawẹ oṣù yìí ninu ọdún? Ìtumọ̀ rẹ ni: Oṣù Ramadan, O sọ pé: Bẹẹni, O sọ pe: Mo n fi Ọlọhun bẹ ọ, ǹjẹ́ Ọlọhun ni O pa ọ láṣẹ ki o gba sàráà yii lọ́wọ́ awọn olowo wa ki o si pin in fun awọn talika wa? Oun naa ni sàká, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: Bẹẹni, Dimaam wa gba Isilaamu, o wa sọ fun Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé oun maa pe ìjọ oun sinu Isilaamu. Lẹ́yìn náà ni o wa ṣe àfihàn ara rẹ pé oun ni Dimaam ọmọ Tha’labah lati ìdílé Banuu Sahd ọmọ Bakr.

فوائد الحديث

Ìtẹríba Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-; torí pé arákùnrin naa ko lee ṣe iyatọ láàárín rẹ àti àwọn saabe rẹ.

Didara ìwà Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati ìwà pẹ̀lẹ́ rẹ nibi fífọ èsì fun ẹni tí ó n bèèrè, ati pe èsì dáadáa wa ninu okùnfà gbigba ipepe.

Ìní ẹtọ ìjúwe èèyàn pẹ̀lú ìròyìn bii funfun ati pupa, ati gíga ati kúkúrú, ati nǹkan ti o jọ ìyẹn nínú nǹkan ti a o gbèrò àléébù pẹ̀lú ẹ, ti ko ba korira ìyẹn.

Ìní ẹtọ fun Kèfèrí láti wọ inu mọṣalaaṣi fun bukaata.

Hajj ko si ninu Hadiisi nitori pe o le ma i tii di dandan ni asiko ti o de.

Ojúkòkòrò àwọn saabe lórí pípe àwọn èèyàn, kété ti o gba Isilaamu ni o ti ni ojúkòkòrò lati pe àwọn èèyàn rẹ.

التصنيفات

Ìgbàgbọ́ ninu Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn, Anọbi wa Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, Ẹsin Isilaamu, Ipepe soju ọna Ọlọhun, Ijẹ dandan irun ati idajọ ẹni ti o ba gbe e ju silẹ, Jijẹ dandan saka yiyọ ati idajọ ẹni ti o ba gbe e ju silẹ, Obligation of Fasting and Ruling of Its Abandoning