Njẹ o maa n gbọ ipe irun?» O sọ pe: Bẹẹ ni, o sọ pe: «Ki o ya dahun

Njẹ o maa n gbọ ipe irun?» O sọ pe: Bẹẹ ni, o sọ pe: «Ki o ya dahun

Lati ọdọ Abu Hurayra – ki Ọlọhun yọnu si i – o sọ pe: Arakunrin afọju kan wa ba Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, o wa sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, ko si ẹni ti yio fa mi wa si mọṣalaṣi, ni o wa bi Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – leere ki o ṣe ẹdẹ fun un ki o maa kirun ni inu ile rẹ, ni o wa ṣe ẹdẹ fun un, nigba ti o wa yi ẹyin pada, o pe e, o wa sọ fun un pe: «Njẹ o maa n gbọ ipe irun?» O sọ pe: Bẹẹ ni, o sọ pe: «Ki o ya dahun».

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Arakunrin afọju kan wa ba Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, o wa sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, ko si lọdọ mi ẹni ti o le maa ran mi lọwọ ti yio si maa fa mi wa si mọṣalaṣi ni asiko awọn irun maraarun, o n wa lati ọdọ Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ki o ṣe ẹdẹ fún un nibi gbigbe irun janmọọn ju silẹ, nigba naa ni o wa ṣe ẹdẹ fun un, nigba ti o wa yi ẹyin pada, o pe e, o wa sọ fun un pe: Njẹ o maa n gbọ ipe irun? O sọ pe: Bẹẹ ni, o sọ pe: Ki o yaa jẹ ipe oluperun.

فوائد الحديث

Ijẹ dandan irun janmọọn; nitori pe ṣiṣe ẹdẹ ko le waye ayaafi nibi nkan ti o ba jẹ dandan ti o si tun jẹ tulaasi.

Gbolohun rẹ: «Fa ajib» fun ẹniti o ba n gbọ ipe ìrun n tọka si ijẹ dandan irun janmọọn; torí pé ìpìlẹ̀ aṣẹ ni ki o maa tumọ si ijẹ dandan.

التصنيفات

Ọla ti o n bẹ fun irun janmọ ati awọn idajọ rẹ