“Ma ṣe maa ni eeyan lara, ma ṣe maa gba ẹsan ìnira, ẹni tí ó bá fi ara ni èèyàn, Ọlọhun yoo fi ara ni in, ẹni tí ó bá ko ìpalára ba èèyàn, Ọlọhun yoo ko ìpalára ba a”

“Ma ṣe maa ni eeyan lara, ma ṣe maa gba ẹsan ìnira, ẹni tí ó bá fi ara ni èèyàn, Ọlọhun yoo fi ara ni in, ẹni tí ó bá ko ìpalára ba èèyàn, Ọlọhun yoo ko ìpalára ba a”

Láti ọ̀dọ̀ Abu Saheed Al-Khudriy- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ma ṣe maa ni eeyan lara, ma ṣe maa gba ẹsan ìnira, ẹni tí ó bá fi ara ni èèyàn, Ọlọhun yoo fi ara ni in, ẹni tí ó bá ko ìpalára ba èèyàn, Ọlọhun yoo ko ìpalára ba a”.

[O ni alaafia pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí rẹ] [Daarukutniy ni o gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dandan ni ki eeyan ti aburu dànù kuro lọ́dọ̀ ara ẹni ati kúrò lọ́dọ̀ ẹlòmíràn, iru inira yòówù ko ri ki o jẹ, ko ni ẹtọ fun ẹnikẹ́ni ki o fi suta kan ara rẹ tabi ẹlòmíràn láìsí iyatọ. Ko si ni ẹtọ fun un ki o fi oró yaró; tori pe a kìí mu inira kúrò pẹ̀lú ìnira ayafi ti a ba fẹ gba ẹsan láìní kọjá ààlà. Lẹyin naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣàlàyé àdéhùn ìyà ìpalára fun ẹni tí ba n ko ìpalára ba àwọn èèyàn, ati ìnira fun ẹni tí ba n ko ìnira ba àwọn èèyàn.

فوائد الحديث

Idinamọ gbigba ẹsan pẹlu nǹkan ti o ju iru aburu ti wọn fi kan èèyàn lọ.

Ọlọhun ko pa ẹrú Rẹ ni àṣẹ pẹlu nǹkan ti o maa ko ìnira ba wọn.

Ṣíṣe ifi inira kan èèyàn ati gbigba ẹsan inira pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tabi ìṣe tabi gbigbe ju silẹ ni eewọ.

Ẹsan maa wa latara ìran iṣẹ, ẹni ti o ba ko ìpalára ba ẹlòmíì, Ọlọhun maa ko ìpalára ba a, ẹni tí ó bá fi ara ni ẹlòmíì, Ọlọhun maa fi ara ni oun naa.

Ọkan ninu awọn ofin Sharia ni pe: “A maa n mu ipalara kuro ni.” Sharia ko fi ọwọ́ si ipalara, o si kọ ipalara.

التصنيفات

Awọn ilana (ofin) agbọye ẹsin ati ilana ipinlẹ agbọye ẹsin. (Awọn akojọpọ imọ agbọye ẹsin ati akojọpọ imọ ipinlẹ agbọye ẹsin)