“Ẹni tí ó bá kó ìpalára ba ẹlòmíràn, Ọlọhun maa ko ìpalára ba oun naa, ẹni tí ó bá ko ìnira ba ẹlòmíràn, Ọlọhun maa ko ìnira ba oun naa”

“Ẹni tí ó bá kó ìpalára ba ẹlòmíràn, Ọlọhun maa ko ìpalára ba oun naa, ẹni tí ó bá ko ìnira ba ẹlòmíràn, Ọlọhun maa ko ìnira ba oun naa”

Láti ọ̀dọ̀ Abu Sirmah- ki Ọlọhun yọnu si i- pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni tí ó bá kó ìpalára ba ẹlòmíràn, Ọlọhun maa ko ìpalára ba oun naa, ẹni tí ó bá ko ìnira ba ẹlòmíràn, Ọlọhun maa ko ìnira ba oun naa”.

[O daa] [Abu Daud ati Tirmiziy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣọ wa lara kuro nibi mimu ìpalára wọlé tọ Musulumi, tabi fifi ìnira kan an nibi èyíkéyìí àlámọ̀rí; yálà nibi ẹ̀mí rẹ ni, tabi dúkìá rẹ, tabi ará-ilé rẹ. Ẹni tí ó bá wa ṣe iyẹn, Ọlọhun maa san an ni ẹsan, O si maa fi ìyà jẹ ẹ ninu iran iṣẹ ti o ṣe.

فوائد الحديث

Ṣíṣe kiko ìpalára ati ìnira ba Musulumi ni eewọ.

Ọlọhun maa n ba àwọn ẹrú Rẹ gba ẹsan.

التصنيفات

Awọn idajọ imu ara ẹni ni ni aayo ati ibọpa bọsẹ fun ara ẹni