“Ẹ ma bu àwọn òkú; torí pé wọn lọ ba nǹkan ti wọn ti síwájú”

“Ẹ ma bu àwọn òkú; torí pé wọn lọ ba nǹkan ti wọn ti síwájú”

Láti ọ̀dọ̀ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹ ma bu àwọn òkú; torí pé wọn lọ ba nǹkan ti wọn ti síwájú”

[O ni alaafia] [Bukhaariy gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe ki a ma maa bú àwọn òkú, ati pe eyi wa ninu awọn iwa buruku; torí pé wọn ti de ibi ti nǹkan ti wọn ti síwájú wa ninu iṣẹ rere tabi buruku, gẹgẹ bi o ṣe jẹ́ pé èébú yii ko lee dé ọdọ wọn, o kan maa kó sùtá ba àwọn alààyè ni.

فوائد الحديث

Hadiisi naa n tọka si ṣíṣe bíbú àwọn òkú ní eewọ.

O n bẹ nibi gbígbé bibu àwọn òkú jù silẹ ṣiṣọ anfaani àwọn alààyè, ati mímú ojú to ààbò àwùjọ kuro nibi ọta ati ìkórìíra.

Ọgbọ́n ti n bẹ nibi kikọ bibu wọn ni pe wọn ti de ibi ti nǹkan ti wọn ti síwájú wa; torí naa eebu wọn ko ṣe anfaani, ati pe sùtá wa nibẹ fun awọn mọ̀lẹ́bí rẹ ti wọn wa láàyè.

Kò lẹtọọ fun ọmọniyan lati maa sọ nǹkan ti ko ba si anfaani ninu ẹ.

التصنيفات

Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ, Iku ati awọn idajọ rẹ