Ẹni ti o ba wa ba yin nigba ti ọrọ yin papọ lori arakunrin kan, ti o wa n gbero láti ya yin, tabi lati pin akojọpọ yin, ki ẹ yaa pa a

Ẹni ti o ba wa ba yin nigba ti ọrọ yin papọ lori arakunrin kan, ti o wa n gbero láti ya yin, tabi lati pin akojọpọ yin, ki ẹ yaa pa a

Lati ọdọ ‘Arfaja – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n sọ pe: «Ẹni ti o ba wa ba yin nigba ti ọrọ yin papọ lori arakunrin kan, ti o wa n gbero láti ya yin, tabi lati pin akojọpọ yin, ki ẹ yaa pa a».

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n ṣe alaye wipe dajudaju ti awọn Musulumi ba kojọ lori olori kan, ati akojọpọ kan, lẹyin naa ni ẹni ti o fẹ ba a du ipo aṣẹ wa de, tabi ti o gbero lati pin awọn Musulumi si ijọ ti o pọ ju ẹyọkan lọ, o jẹ dandan fun wọn lati kọ fun un ati lati ba a ja; lati fi ti aburu rẹ danu ati lati fi da aabo bo ẹjẹ awọn Musulumi.

فوائد الحديث

Jijẹ dandan gbigbọ ati titẹle alaṣẹ (oludari) awọn Musulumi nibi nkan ti kii ṣe ẹṣẹ, ati jijẹ eewọ jijade le e lori.

Ẹni ti o ba jade lori asiwaju awọn Musulumi ati akojọpọ wọn, dajudaju o jẹ dandan lati ba a ja bo ti le wu ki ipo rẹ o to ni ti iyi ati iran.

Ṣiṣenilojukokoro lori akojọpọ ati aisi ituka ati iyapa.

التصنيفات

Jijade si imam