إعدادات العرض
“Ti Mùsùlùmí méjì ba pàdé ara wọn pẹ̀lú idà, ati ẹni ti o pa eeyan ati ẹni tí wọ́n pa, wọn jọ maa wọ iná ni
“Ti Mùsùlùmí méjì ba pàdé ara wọn pẹ̀lú idà, ati ẹni ti o pa eeyan ati ẹni tí wọ́n pa, wọn jọ maa wọ iná ni
Láti ọ̀dọ̀ Abu Bakrah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: “Ti Mùsùlùmí méjì ba pàdé ara wọn pẹ̀lú idà, ati ẹni ti o pa eeyan ati ẹni tí wọ́n pa, wọn jọ maa wọ iná ni”, mo wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, a gbọ ti ẹni tí o pa èèyàn, ẹni tí wọ́n pa wa nkọ? O sọ pé: “Oun naa fẹ́ pa ẹni keji rẹ ni”.
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी ئۇيغۇرچە Kurdî Hausa Português മലയാളം తెలుగు Kiswahili မြန်မာ Deutsch 日本語 پښتو Tiếng Việt অসমীয়া Shqip Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands සිංහල தமிழ் ไทย دری Fulfulde Magyar Italiano ಕನ್ನಡ Кыргызча Lietuvių Malagasy or Română Kinyarwanda Српски тоҷикӣ O‘zbek Moore नेपाली Oromoo Wolof Soomaali Български Українська Azərbaycan bm ქართული Македонскиالشرح
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ti Mùsùlùmí meji ba pade ara wọn pẹ̀lú idà, ti ìkíni kejì wọn n gbero lati pa ìkejì rẹ; ẹni tí ó pa èèyàn maa wọ iná; tori pe oun ni o pa ikeji rẹ tààrà, Ọ̀rọ̀ ẹni tí wọ́n pa wa ru àwọn saabe lójú pe: Báwo ni o ṣe maa wọ ina? Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé torí pé oun naa fẹ́ pa ìkejì rẹ ni, ko si si nǹkan ti o kọ̀ fun un lati ma pa a ju pe ọwọ́ ẹni tí o pa a yá ju tiẹ̀ lọ ni.فوائد الحديث
Ìní-ẹ̀tọ́ si ìyà ẹni ti o ba pinnu láti da ẹ̀ṣẹ̀ nínú ọkàn rẹ ti o si ṣe àwọn okùnfà rẹ tààrà.
Ikilọ ti o lágbára kúrò nibi ki awọn Mùsùlùmí maa ba ara wọn ja, ati àdéhùn ìyà iná lori ẹ.
Ìjà láàárín àwọn Musulumi pẹlu ẹ̀tọ́ kò kó sínú adehun ìyà naa, gẹgẹ bii bíbá àwọn ti o kọjá ẹnu-ala jà ati awọn obilẹjẹ.
Ẹni ti o ba da ẹṣẹ ńlá ko nii di Kèfèrí pẹlu ọ̀wọ́ pé ó kàn dá ẹṣẹ naa; torí pé Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe àwọn ti wọn n ba ara wọn jà ni Musulumi.
Ti Musulumi meji ba pade ara wọn pẹ̀lú èyíkéyìí nǹkan ti wọn le fi pa èèyàn, ti ọkan ninu wọn wa pa ikeji, ẹni ti o pa èèyàn ati ẹni tí wọ́n pa maa wọ ina, wọn kan dárúkọ idà ninu hadiisi naa lati fi ṣe àpèjúwe ni.