“Dájúdájú Ọlọhun ko nii wo àwòrán yin ati dúkìá yin, ṣùgbọ́n O maa wo ọkàn yin ati iṣẹ yin”

“Dájúdájú Ọlọhun ko nii wo àwòrán yin ati dúkìá yin, ṣùgbọ́n O maa wo ọkàn yin ati iṣẹ yin”

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dájúdájú Ọlọhun ko nii wo àwòrán yin ati dúkìá yin, ṣùgbọ́n O maa wo ọkàn yin ati iṣẹ yin”.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ko nii wo àwòrán ẹrú ati ara wọn, boya o rẹwà ni abi o burẹ́wà? Boya o tobi ni abi o kéré? Bóyá o ni alaafia ni abi o n ṣe àìsàn? Ko si nii wo dúkìá wọn, bóyá o pọ ni abi o kéré? Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn ko nii fi àwọn nǹkan wọ̀nyí bi àwọn ẹrú Rẹ, ko si nii ṣe ìṣirò wọn lórí rẹ ati bi wọn ṣe yatọ si ara wọn nínú ẹ, ṣùgbọ́n O maa wo ọkàn wọn ati nǹkan ti o wa ninu ẹ bii ipaya ati àmọ̀dájú, ati ododo ati imọkanga, tabi gbigbero ṣekarimi ati ṣekagbọmi, O si tun maa wo iṣẹ wọn bóyá o dára ni abi ko dára, O maa wa sẹsan lori ẹ.

فوائد الحديث

Ìní akolekan si titun ọkàn ṣe, ati mimọ ọn kuro nibi gbogbo ìròyìn burúkú.

Dídára ọkàn pẹ̀lú imọkanga ni, dídára iṣẹ pẹ̀lú itẹle Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni, àwọn méjèèjì yii ni Ọlọhun maa wò.

Ọmọniyan ko gbọdọ gba ẹtan pẹ̀lú dúkìá rẹ tabi ẹwà rẹ tabi ara rẹ, tabi nǹkan kan ninu àwòrán ayé yii.

Ikilọ kuro nibi ifayabalẹ lori ìta ti o hàn lai tún inú ti o pamọ ṣe.

التصنيفات

Taohiid ti àwọn orúkọ ati awọn iroyin, Awọn iṣẹ ọkan