“Ìwọ Ọlọhun, ẹnikẹni ti o ba jẹ alaṣẹ lori nǹkan kan ninu ijọ mi, ti o wa fi ara ni wọn, ki O fi ara ni in, ẹnikẹni ti o ba jẹ alaṣẹ lori nǹkan kan ninu ijọ mi, ti o wa ṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú wọn, ṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú oun naa”

“Ìwọ Ọlọhun, ẹnikẹni ti o ba jẹ alaṣẹ lori nǹkan kan ninu ijọ mi, ti o wa fi ara ni wọn, ki O fi ara ni in, ẹnikẹni ti o ba jẹ alaṣẹ lori nǹkan kan ninu ijọ mi, ti o wa ṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú wọn, ṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú oun naa”

Lati ọdọ Aisha- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ lẹ́nu ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n sọ ninu ilé mi yii pe: “Ìwọ Ọlọhun, ẹnikẹni ti o ba jẹ alaṣẹ lori nǹkan kan ninu ijọ mi, ti o wa fi ara ni wọn, ki O fi ara ni in, ẹnikẹni ti o ba jẹ alaṣẹ lori nǹkan kan ninu ijọ mi, ti o wa ṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú wọn, ṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú oun naa”.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣẹ èpè lé gbogbo ẹni tí ó bá jẹ alaṣẹ lori àlámọ̀rí kan fun awọn Mùsùlùmí, bóyá o kéré ni tabi o tóbi, bóyá ti gbogbogboo ni tabi fun apá ibikan sọ́, tí o wa fi ara ni wọn ti ko ṣàánú wọn, pe Ọlọhun ti ọla Rẹ ga maa san an lẹsan latara irú iṣẹ rẹ pẹlu pe ki o fi ara ni oun náà. Ẹni tí ó bá wa ṣàánú wọn ti o si ṣe àlámọ̀rí wọn ni irọrun, pe ki Ọlọhun ṣàánú tiẹ̀ naa ki O si ṣe àlámọ̀rí rẹ ni irọrun.

فوائد الحديث

O di dandan fún ẹni tí o ba jẹ alaṣẹ lori nnkan kan ninu àlámọ̀rí àwọn Musulumi ki o ṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú wọn bi o ba ṣe kápá mọ.

Ẹsan maa wa latara iran iṣẹ.

Òṣùwọ̀n ohun ti a maa kà kún ninu ìwà pẹ̀lẹ́ tabi ilekoko ni ohun ti ko ba ti tako Kuraani ati Sunna.

التصنيفات

Awọn majẹmu jijẹ imam ti o tobi, Awọn majẹmu jijẹ imam ti o tobi, ‏Aanu rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-, ‏Aanu rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-